1 Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹrin tí mo di ọmọ ọgbọ̀n ọdún tí mo wà láàrin àwọn ìgbèkùn ní etí òdò Kébárì, àwọn ọ̀run sí sílẹ̀, mo sì rí ìran Ọlọ́run.
2 Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù—tí ó jẹ́ ọdún karùn-ún ìgbèkùn Ọba Jehóákímù—
3 ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ àlùfáà Ísíkẹ́lì, ọmọ Búsì wá, létí odò Kébárì ni ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì. Níbẹ̀ ni ọwọ́ Olúwa ti wà lára rẹ̀.
4 Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùukùu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárin iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná,
5 àti láàrin iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin (4) wà: Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn,
6 ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin.
7 Ẹsẹ̀ wọn sì tọ́; àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì rí bí ti ọmọ màlúù, wọ́n sì tàn bí awọ idẹ dídán.