3 ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ àlùfáà Ísíkẹ́lì, ọmọ Búsì wá, létí odò Kébárì ni ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì. Níbẹ̀ ni ọwọ́ Olúwa ti wà lára rẹ̀.
4 Mo wò, mo sì rí ìjì tó ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá ìkùukùu tó nípọn pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná bù yẹ̀rì pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ rokoṣo tó yí i ká. Àárin iná náà rí bí ìgbà tí irin bá ń bẹ nínú iná,
5 àti láàrin iná náà ni ohun tó dàbí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin (4) wà: Ìrísí wọn jẹ́ ti ènìyàn,
6 ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin.
7 Ẹsẹ̀ wọn sì tọ́; àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì rí bí ti ọmọ màlúù, wọ́n sì tàn bí awọ idẹ dídán.
8 Ní abẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọn ní ọwọ́ ènìyàn. Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú àti àwọn ìyẹ́,
9 ìyẹ́ wọn kan ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò padà lọ́nà ibi tí ó ń lọ; ṣùgbọ́n wọ́n ń lọ tààrà ni.