13 Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn kẹ̀kẹ́ yìí ni “kẹ̀kẹ́ ìpòòyì.”
14 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kérúbù yìí ni ojú mẹ́rin: ojú èkínní jẹ́ ojú kérúbù, ojú kejì jẹ́ ti ènìyàn, ojú kẹta jẹ́ ti kìnnìún nígbà tí ojú kẹrin jẹ́ ti ẹyẹ idì.
15 A gbé àwọn kérúbù sókè. Èyí ni àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo rí létí odò Kébárì.
16 Bí àwọn kérúbù yìí bá ń lọ àwọn kẹ̀kẹ́ ẹgbẹ́ wọn náà yóò lọ; bẹ́ẹ̀ ni bí àwọn kérúbù bá tú ìyẹ́ wọn ká láti dìde nílẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ yìí kò ní kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.
17 Bí àwọn kérúbù bá dúró díẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dúró jẹ́ẹ́; bí àwọn kérúbù bá dìde àwọn kẹ̀kẹ́ náà yóò dìde, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè yìí wà nínú wọn.
18 Ògo Olúwa kúrò níbi ìloro tẹ́ḿpìlì ó sì dúró sórí àwọn kérúbù.
19 Àwọn kérúbù gbé ìyẹ́ wọn sókè, wọ́n sì fò kúrò nílẹ̀ lójú mi, wọ́n sì lọ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ wọn lẹ́ẹ̀kan náà. Wọ́n dúró níbi ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà ìlà-oòrùn ilé Olúwa, ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì wà lórí wọn.