3 Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Ègbé ni fún àwọn òmùgọ̀ wòlíì tó ń tẹ̀lé ẹ̀mí ara wọn tí wọn kò sì rí nǹkankan!
4 Ísirẹ́lì àwọn wòlíì rẹ dàbí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ nínú pápá.
5 Ẹ kò gòkè láti mọ odi tí ó ya ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì kí wọ́n ba lè dúró gbọin lójú ogun lọ́jọ́ Olúwa.
6 Ìran àti àfọ̀ṣẹ wọn jẹ́ èké. Wọ́n wí pé, “Olúwa wí” nígbà tí Olúwa kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n fẹ́ kí Olúwa mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.
7 Ẹ̀yin kò ha ti rí ìran asán, ẹ kò ha ti fọ àfọ̀ṣẹ èké, nígbà tí ẹ sọ pé, “Olúwa wí,” bẹ́ẹ̀ sì ni Èmi kò sọ̀rọ̀?
8 “ ‘Nítorí náà báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nítorí ọ̀rọ̀ asán àti ìran èké yín, mo lòdì sí yín: ni Olúwa Ọlọ́run wí.
9 Ọwọ́ mi yóò sì wà lórí àwọn wòlíì tó ń ríran asán, tó sì ń sọ àfọ̀ṣẹ èké. Wọn kò ní sí nínú ìjọ àwọn ènìyàn mi, a ó sì yọ orúkọ wọn kúrò nínú àkọsílẹ̀ ilé Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì ní wọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́. Nígbà náà ni ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run.