Ísíkẹ́lì 17:12-18 BMY

12 “Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí, ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Sọ fún wọn: ‘Ọba a Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kó Ọba àti àwọn ìjòyè ọmọ aládé ibẹ̀ lọ sí Bábílónì lọ́dọ̀ rẹ̀.

13 Lẹ́yìn èyí ó bá ọ̀kan nínú ọmọ Ọba dá májẹ̀mú, ó mú un jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìbúra ó tún kó àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà.

14 Kí ìjọba ilẹ náà le re lẹ̀, láì ní le gbérí mọ́, àyàfi tí ó bá pa májẹ̀mú rẹ mọ ni yóò tó ó lè dúró.

15 Ṣùgbọ́n Ọba ṣọ̀tẹ̀ sí i nípa ríran aṣojú lọ sí Éjíbítì, kí wọn bá à lè fún-un ni ẹsin àti àwọn ọmọ ogun púpọ̀. Yóò ha ṣe àṣeyorí? Ṣe ẹni tó ṣe irú nǹkan yìí yóò sì bọ́ níbẹ̀? Yóò wá da májẹ̀mú kó sì bọ́ níbẹ̀ bí?

16 “ ‘Bí mo ti wà láàyè ni Olúwa Ọlọ́run wí, níbi tí Ọba tó fi sórí oyè wà, ẹ̀jẹ́ ẹni tí ó kẹ́gàn àti májẹ̀mú ẹni tí ó dà, níbẹ̀ ni àárin Bábílónì ní yóò kùú sí.

17 Nígbà tí wọ́n bá pa bùdó ogun tì í, tí wọ́n sì mọ odi láti pa ọ̀pọ̀ ènìyàn, Fáráò pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àti àjọ ńlá rẹ̀ kò ní lè ṣe ìrànwọ́ fún-un lójú ogun.

18 Nítorí pé ó kẹ́gàn ẹ̀jẹ́ nípa dída májẹ̀mú, àti pé ó juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ìlérí, kò ní i bọ níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan to ṣe yìí.