8 Orí ilẹ̀ tó dára lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ni a gbìn ín sí, kí ó bá à le pẹ̀ka, kò sí so èso, ó sì wá di igi àjàrà tó lọ́lá púpọ̀.’
9 “Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí nìyí: Yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì ní gba agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòngbò rẹ̀ tu.
10 Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí? Kò wá ní i rọ pátapáta nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà oòrùn bá kọ lù ú. Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà?’ ”
11 Nígbà náà, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá pé:
12 “Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí, ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Sọ fún wọn: ‘Ọba a Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kó Ọba àti àwọn ìjòyè ọmọ aládé ibẹ̀ lọ sí Bábílónì lọ́dọ̀ rẹ̀.
13 Lẹ́yìn èyí ó bá ọ̀kan nínú ọmọ Ọba dá májẹ̀mú, ó mú un jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìbúra ó tún kó àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà.
14 Kí ìjọba ilẹ náà le re lẹ̀, láì ní le gbérí mọ́, àyàfi tí ó bá pa májẹ̀mú rẹ mọ ni yóò tó ó lè dúró.