29 Síbẹ̀, ilé Ísírẹ́lì wí pé, ‘Ọ̀nà Olúwa kò tọ́.’ Ọ̀nà mi kò ha tọ́ bí Ilé Ísírẹ́lì? Kì í wa se pè ọ̀nà tiyín gan an ni ko tọ?
30 “Nítorí náà, ilé Ísírẹ́lì, n ó da yín lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ẹnì kọ̀ọ̀kan yín bá ṣe rí ni Olúwa Ọlọ́run wí. Yípadà! Kí ẹ si yí kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀ṣẹ̀ ma ba a jẹ́ ọ̀nà ìsubú yín.
31 Ẹ kọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti ẹ ti dá sílẹ̀, kí ẹ sì gba ọkàn àti ẹ̀mi tuntun. Nitori kí ló fi máa kú, ilé Ísírẹ́lì?
32 Nítorí pé inú mi kò dùn sí ikú ẹnikẹ́ni ni Olúwa Ọlọ́run wí. Nítorí náà, ẹ yípadà kí ẹ sì yè!