16 Nítorí pé wọn kọ òfin mi sílẹ̀, wọn kò sì tẹ̀lé àsẹ mi, wọn sọ ọjọ́ ìsinmi mi dí aláìmọ́. Nítorí pé tọkàntọkàn ni wọn ń tẹ̀lé òrìṣà wọn.
17 Síbẹ̀síbẹ̀ mo wò wọ́n pẹ̀lú àánú, ń kò sì pa wọ́n run tàbí kí òpin dé bá wọn nínú ihà.
18 Ṣùgbọ́n mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú ihà pé, “Ẹ má ṣe rìn ní ìlànà àwọn baba yín tàbí kí ẹ pa òfin wọn mọ́ tàbí kí ẹ bara yín jẹ́ pẹ̀lú òrìṣà wọn.
19 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ó sì pa òfin mi mọ́.
20 Ẹ ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́ kí ó lè jẹ́ àmì láàrin wa: ki ẹ lè mọ̀ pé èmi ní Olúwa Ọlọ́run yín.”
21 “ ‘Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Wọn kò tẹ̀lé àṣẹ mi, wọn kò sì pa òfin mí mọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó bá tẹ̀lé àwọn òfin yìí, yóò yè nínú rẹ̀, wọ́n sì tún sọ ọjọ́ ìsinmi mi di aláìmọ́. Nítorí náà, mo sọ pé ń ó tú ìbínú mi lórí wọn N ó sì mú kí ibínú gbígbóná mi wá sórí wọn ni ihà.
22 Síbẹ̀síbẹ̀ mo dáwọ́ dúró, nitori orúkọ mi mo sì ṣe ohun tí kò ní bá orúkọ mi jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè ti mo kó wọn jáde lójú wọn.