37 Èmi yóò kíyèsí i yín bí mo ti mú un yín kọjá lábẹ́ ọ̀pá, èmi yóò sì mú yín wá sí abẹ́ ìdè májẹ̀mú
38 Èmi yóò ṣa àwọn tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí mí kúrò láàrin yín. Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé èmi yóò mú wọn kúrò ní ilẹ̀ tí wọn ń gbé, síbẹ̀ wọn kò ní dé ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ní Olúwa.
39 “ ‘Ní tí ẹ̀yin, ilé Ísírẹ́lì, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Kí olúkúlùkù yín lọ máa sìn òrìṣà rẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, ẹ̀yin yóò gbọ́ tèmi, ẹ̀yin kò sí ní i bá orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ọrẹ àti àwọn òrìṣà yín mọ́.
40 Nítorí lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Ísírẹ́lì, ni Olúwa Ọlọ́run wí, níbẹ̀ ni ilẹ̀ náà ní gbogbo ilé Ísírẹ́lì yóò sìn mí; n ó sì tẹ́wọ́ gba wọ́n níbẹ̀. Níbẹ̀ ń ó bèèrè ọrẹ àti ẹ̀bùn nínú àkọ́so yín pẹ̀lú gbogbo ẹbọ mímọ́ yín
41 N o tẹ́wọ́ gbà yín gẹ́gẹ́ bí tùràrí olóórùn dídùn nígbà tí mo ba mú yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí a fọ́n yín ká sí, ń ó sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrin yín lójú àwọn orilẹ̀ èdè.
42 Nígbà náà ni ẹ o mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá mú yín wa sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì; sí ilẹ̀ tí mo gbọ́wọ́ mí sókè nínú ẹ̀jẹ́ láti fún àwọn baba yín.
43 Níbẹ̀ ni ẹ ó wa rántí ìwà àti gbogbo ìsesí yín, èyí tí ẹ̀yin fi sọ ara yín di aláìmọ́, ẹ̀yin yóò sì kóríra ara yín fún gbogbo ibi tí ẹ̀yin ti se.