41 N o tẹ́wọ́ gbà yín gẹ́gẹ́ bí tùràrí olóórùn dídùn nígbà tí mo ba mú yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀ èdè tí a fọ́n yín ká sí, ń ó sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrin yín lójú àwọn orilẹ̀ èdè.
42 Nígbà náà ni ẹ o mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá mú yín wa sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì; sí ilẹ̀ tí mo gbọ́wọ́ mí sókè nínú ẹ̀jẹ́ láti fún àwọn baba yín.
43 Níbẹ̀ ni ẹ ó wa rántí ìwà àti gbogbo ìsesí yín, èyí tí ẹ̀yin fi sọ ara yín di aláìmọ́, ẹ̀yin yóò sì kóríra ara yín fún gbogbo ibi tí ẹ̀yin ti se.
44 Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá hùwà sí yín nítorí orúkọ mi ni, tí ń kò hùwà sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ibi àti ìwà ìríra yín. Ẹ̀yin Ilé Ísírẹ́lì, ni Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”
45 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
46 “Ọmọ ènìyàn, dojú kọ ìhà gúsù; wàásù lòdì sí gúsù kí ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ sí igbó ilẹ̀ gúsù.
47 Sọ fún igbo ìhà gúsù: ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí ní ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsí í, èmi yóò dá iná kan nínú rẹ̀ yóò sì jó olúkúlùkù igi tutu nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù igi gbígbẹ. Jíjí ọwọ́ iná náà kò ní i ṣe e pa, àti gbogbo ojú láti gúsù dé aríwá ni a ó sun nínú rẹ̀.