44 Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá hùwà sí yín nítorí orúkọ mi ni, tí ń kò hùwà sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ibi àti ìwà ìríra yín. Ẹ̀yin Ilé Ísírẹ́lì, ni Olúwa Ọlọ́run wí.’ ”
45 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
46 “Ọmọ ènìyàn, dojú kọ ìhà gúsù; wàásù lòdì sí gúsù kí ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ sí igbó ilẹ̀ gúsù.
47 Sọ fún igbo ìhà gúsù: ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Èyí ní ohun tí Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsí í, èmi yóò dá iná kan nínú rẹ̀ yóò sì jó olúkúlùkù igi tutu nínú rẹ̀, àti olúkúlùkù igi gbígbẹ. Jíjí ọwọ́ iná náà kò ní i ṣe e pa, àti gbogbo ojú láti gúsù dé aríwá ni a ó sun nínú rẹ̀.
48 Gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé Èmi Olúwa ni ó dá a, a kì yóò sì le è pa á.’ ”
49 Nígbà náà ni mo wí pé, “Áà! Olúwa Ọlọ́run! Wọn ń sọ fún mi pé, ‘Kì í wa ṣe pé òwe lo ń pa bí?’ ”