5 Nígbà náà gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti yọ idà mi kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; kì yóò sì padà sínú rẹ̀ mọ́.’
6 “Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mi ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn.
7 Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mi ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
9 “Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ wí pé, Èyí yìí ní Olúwa wí:“ ‘Ìdá kan, Ìdá kan,tí a pọ́n tí a sì kùn
10 a ti pọ́n fún pípa,a sì dan an kí ó lè máa kọ bí mọ̀nàmọ́ná!“ ‘Àwa yóò ha si ọ̀pá aládé ọmọ mi Júdà? Idà kẹ́gàn gbogbo ọ̀pá.
11 “ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n,kí ó lè ṣe é gbá mú;a pọ́n ọn a sì dan án,ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani.