14 Ǹjẹ́ ìwọ yóò lè ní ìgboyà tó, tàbí ọwọ́ rẹ yóò ni agbára ní ọjọ́ tí èmi yóò ni ṣíṣe pẹ̀lú rẹ? Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, Èmi yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀.
15 Èmi yóò tú kán ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò fọ́n ọ ká sí àwọn ìlú; èmi yóò sì fi òpin sí àìmọ́ rẹ.
16 Nígbà tí a ó bà ọ́ jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀ èdè, ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”
17 Nígbà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
18 “Ọmọ ènìyàn, ilé Ísírẹ́lì ti di ìdárọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, tánúnganran, ìrin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà.
19 Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdárọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jérúsálẹ́mù.
20 Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti tánúnganran jọ sínú iná ìléru láti fi amúbí ina yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunnú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárin ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́.