36 Olúwa sọ fún mi pé: “Ọmọ ènìyàn, ń jẹ́ ìwọ yóò ṣe ìdájọ́ Óhólà àti Óhólíbà? Nítorí náà dojú kọ wọn nípa ìkórìíra tí wọn ń ṣe,
37 nítorí wọn ti dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà ẹ̀jẹ̀ sì wà ní ọwọ́ wọn. Wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà pẹ̀lú àwọn orìṣà wọn; kódà wọ́n fi àwọn ọmọ wọn tí wọn bí fúnni ṣe ìrúbọ, gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún wọn.
38 Bákan náà ni wọ́n ti ṣe èyí náà sí mi: Ní àkókò kan náà wọn ba ibi mímọ́ mi jẹ́, wọ́n sì lo ọjọ́ ìsinmi mi ní àìmọ́.
39 Ní ọjọ́ náà gan an wọ́n fi àwọn ọmọ wọn rúbọ sí àwọn òrìṣà, wọn wọ ibi mímọ́ mi lọ wọn sì lò ó ní ìlòkúlò. Ìyẹn ní wọn ṣe ní ilé mi.
40 “Wọn tilẹ̀ rán oníṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn, nígbà tí wọ́n dé, ìwọ wẹ ara rẹ fún wọn, ìwọ kún ojú rẹ, ìwọ sì fi ọ̀sọ́ iyebíye sára,
41 Ìwọ jókòó lórí ibùsùn ti o lẹ́wà, pẹ̀lú tábìlì tí a tẹ́ ní iwájú rẹ lórí, èyí tí o gbé tùràrí àti òróró tí ó jẹ́ tèmi kà.
42 “Ariwo ìjọ ènìyàn tí kò bìkítà wà ní àyíká rẹ̀; a mú Sábéánì láti ihà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin láti ara àwọn ọ̀pọ̀ èniyàn aláìníláárí, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀gbà ọrùn ọwọ́ sí àwọn ọwọ́ obìnrin náà àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, adé dárádárá sì wà ní orí wọn.