Ísíkẹ́lì 25:3-9 BMY

3 Sì wí fún àwọn ará Ámónì pé, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run tí ó wí pé: Nítorí tí ìwọ wí pé, “Á hà!” Sí ibi mímọ́ mi nígbà tí ó di àìlọ́wọ̀ àti sí orí ilẹ̀ Ísírẹ́lì nígbà tí ó di ahoro; àti sí ilẹ̀ Júdà, nígbà tí wọ́n lọ sí ìgbèkùn,

4 kíyèsí i, nítorí náà ni èmi yóò fi fi ọ lé àwọn ènìyàn ìlà oòrùn lọ́wọ́ ni ohun ìní. Wọn yóò sì gbé ààfin wọn kalẹ̀ nínú rẹ, wọn yóò sì gbé ibùgbé wọn nínú rẹ: wọn yóò jẹ èso rẹ, wọn yóò sì mu wàrà rẹ.

5 Èmi yóò sì sọ Rábà di ibùjẹ, fún àwọn ìbákasíẹ àti àwọn ọmọ Ámónì di ibùsùn fún agbo ẹran. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.

6 Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: Nítorí pé ìwọ pàtẹ́wọ́, ìwọ sì jan ẹsẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ìwọ ń yọ̀ pẹ̀lú gbogbo àrankàn rẹ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì

7 nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mi lé ọ, èmi yóò sì fi ọ fún àwọn aláìkọlà fún ìkógun. Èmi yóò sì gé ọ kúrò láàrin àwọn ènìyàn, èmi yóò sì jẹ́ kí o parun kúrò ni ilẹ̀ gbogbo. Èmi yóò sì pa ọ́ run, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

8 “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí: ‘Nítorí pé Móábù àti Séírì sọ wí pé, “Wò ó, ilé Júdà ti dàbí gbogbo àwọn aláìkọlà,”

9 nítorí náà Èmi yóò sí Móábù sílẹ̀ láti àwọn ìlú gbogbo tí ó wà ní ààlà rẹ̀, ògo ilẹ̀ náà, Bétjẹ́símótì, Báálì-Méónì àti Kíríátaímù.