19 “ ‘Àwọn ará Dánì àti Gíríkì láti Úsálì ra ọjà títà rẹ; irin dídán, káṣíà ati kálámù ni àwọn ohun pàsípààrọ̀ ní ọjà rẹ.
20 “ ‘Dédánì ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.
21 “ ‘Àwọn ará Árábù àti gbogbo àwọn ọmọ aládé Kédárì àwọn ni àwọn onibárà rẹ: ní ti ọ̀dọ́ àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbárà rẹ.
22 “ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣébà àti Rámà, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.
23 “ ‘Áránì àti Kánnà àti Édénì, àwọn onísòwò Ṣébà, Ásúrù àti Kílímádì, ni àwọn oníṣòwò rẹ.
24 Wọ̀nyí ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oniṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ oníyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kédárì ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.
25 “ ‘Àwọn ọkọ̀ Táṣíṣì ní èròní ọjà rẹa ti mú ọ gbilẹ̀a sì ti ṣe ọ́ lógoní àárin gbungbun òkun