2 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún fún Tírè.
3 Sọ fún Tírè, tí a tẹ̀dó sí ẹnu bodè òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní Olúwa Ọlọ́run wí:“ ‘Ìwọ Tírè wí pé“Ẹwá mi pé.”
4 Ààlà rẹ wà ní àárin òkun;àwọn ọ̀mọ̀lé rẹ ti mú ẹwà rẹ pé.
5 Wọn ti fi pákó firi ti Sénárìkan gbogbo ọkọ̀ rẹ,wọ́n ti mú kédárì ti Lébánónì wáláti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ.
6 Nínú igi Oákù ti Báṣánìní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ òbèlè rẹ̀;ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lúigi bókísì láti erékùsù Kítímù wá
7 Asọ funfun dáradára tí a fi abẹ́rẹ́ṣiṣẹ́ ọ̀nà sí lára láti Éjíbítì wáni èyí tí ìwọ ta láti se okun ọkọ̀aṣọ aláró àti elésèé àlùkòláti erékùṣù ti Èlíṣàni èyí tí a fi bò ó
8 Àwọn ará ìlú Sídónì àti Árífádì ni àwọn ìtukọ̀ rẹ̀àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tírè,tí wọ́n wà nínú rẹ ni àwọn àtukọ̀ rẹ.