23 “ ‘Áránì àti Kánnà àti Édénì, àwọn onísòwò Ṣébà, Ásúrù àti Kílímádì, ni àwọn oníṣòwò rẹ.
24 Wọ̀nyí ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oniṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ oníyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi kédárì ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.
25 “ ‘Àwọn ọkọ̀ Táṣíṣì ní èròní ọjà rẹa ti mú ọ gbilẹ̀a sì ti ṣe ọ́ lógoní àárin gbungbun òkun
26 Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọwá sínú omi ńlá.Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ní àárin gbùngbùn òkun.
27 Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ,àwọn atọ́kọ̀ rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ.Àwọn oníbárà rẹ àti gbogbo àwọnjagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹàti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹtí ó wà ní àárin rẹyóò rì sínú àárin gbùngbùn òkunní ọjọ́ ìparun rẹ.
28 Ilẹ̀ etí òkun yóò mìnítorí ìró igbe àwọn atọ́kọ̀ rẹ.
29 Gbogbo àwọn alájẹ̀àwọn atukọ̀àti àwọn atọ́kọ̀ ojú òkun;yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn,wọn yóò dúró lórí ilẹ̀.