3 Nítorí ọjọ́ náà sún mọ́ tòsíàní ọjọ́ Olúwa sún mọ́ tòsíỌjọ́ tí ọjọ́ ìkùukùu ṣú dúdú,àsìkò ìparun fún àwọn aláìkọlà
4 Idà yóò wá sórí Éjíbítììrora ńlá yóò sì wá sórí KúṣìNígbà tí àwọn tí a pa yóò subú ní Éjíbítìwọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀.
5 Kúṣì àti Pútì, Lídíà àti gbogbo Árábù, Líbíyà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ ìlérí yóò ṣubú nípa idà papọ̀ pẹ̀lú Éjíbítì.
6 “ ‘Èyí yìí ní Olúwa wí:“ ‘Àwọn alejò Éjíbítì yóò ṣubúagbára ìgbéraga rẹ yóò kùnàláti Mígídólì títí dé Ásúwánìwọn yóò ti ipa idà ṣubú láàárin rẹ;ní Olúwa Ọlọ́run wí:
7 Wọn yóò sì wàlára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro,ìlú rẹ yóò sì wàní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro.
8 Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ijíbítìtí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun.
9 “ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kúsì kúrò nínú ìtẹ́lọ́rùn rẹ̀. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Éjíbítì: Kíyèsí i, ó dé.