1 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kejìlá, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
2 “Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Fáráò Ọba Éjíbítì kí o sì wí fún un:“ ‘Ìwọ dàbí kìnnìún láàárin àwọnorílẹ̀ èdè náà;ìwọ dàbí ohun abanilẹ́rù inú àwọn okun to ń lọkáàkiri inú àwọn odò rẹ,ìwọ fi ẹsẹ rẹ tẹ omiláti mú kí àwọn odò ní ẹrẹ̀.
3 “ ‘Èyí yìí ńi Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:“ ‘Pẹ̀lu ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyànÈmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi.
4 Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀èmi yóò sì fà ọ́ sókè sí orí pápá gbangba.Èmi yóò jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ṣeàtìpó ní orí rẹ.Gbogbo àwọn ẹranko ayé yóò fiìwọra gbé ara wọn mù lórí rẹ.
5 Èmi yóò tan ẹran ara rẹ ká sóríàwọn òkè gígaìyókù ara rẹ ní wọn yóò fi kúnàwọn àárin àwọn òkè gíga
6 Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń ṣàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náàgbogbo ọ̀nà sí orí àwọn òkè gíga,àwọn àlàfo jínjìn ní wọn yóò kún fún ẹran ara rẹ.
7 Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run déàwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn;èmi yóò sì fi ìkùukùu bo oòrùnòṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀