15 Nígbà tí mo bá sọ Éjíbítì di ahoro,tí mo sì kó gbogbo ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀ náà kúrò.Nígbà tí mo bá gé àwọn olùgbé ibẹ̀ lulẹ̀,nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’
16 “Èyí yìí ni ẹkún tí a óò sun fún un. Àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀ èdè yóò sun ún; nítorí Éjíbítì àti gbogbo ìjọ rẹ, wọn yóò sun ún, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
17 Ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ mí wá:
18 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún ìjọ Éjíbítì kí o sì ránsẹ́ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti òun àti àwọn ọmọbìnrin orílẹ̀ èdè alágbára, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ìsàlẹ̀, kòtò.
19 Sọ fún wọn, ‘Ǹjẹ ìwọ ní ojú rere jù àwọn tí o kù lọ? Lọ sí ìsàlẹ̀ kí a sì tẹ́ ọ sí àárin àwọn aláìkọlà náà.’
20 Wọn yóò ṣubú láàárin àwọn tí a fi idà pa. A fa idà yọ; jẹ́ kí a wọ́ Éjíbítì kúrò pẹ̀lú gbogbo ìjọ rẹ̀.
21 Láti inú isà òkú alágbára tí í ṣe aṣáájú yóò sọ nípa Éjíbítì àti àwọn àlejò rẹ̀, ‘Wọn ti wá sí ìsàlẹ̀, wọn sì sùn pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.’