28 “Ìwọ náà, Fáráò, ní yóò ṣẹ, ti yóò dùbúlẹ̀ láàárin aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.
29 “Édómù wà níbẹ̀, àwọn Ọba rẹ̀ àti gbogbo ọmọbìnrin Ọba; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní agbára, a tẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa. Wọn dùbúlẹ̀ pẹ̀lú aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn ti o lọ sínú kòtò.
30 “Gbogbo àwọn ọmọ aládé ilẹ̀ àríwá àti gbogbo àwọn ará Sídónì wà níbẹ̀; wọn lọ sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí a pa ní ìtìjú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ṣe okùnfà ẹ̀rù pẹ̀lú agbára wọn. Wọn sùn ní àìkọlà pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa, wọn sì ru ìtìjú wọn pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò.
31 “Fáráò, òun àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ óò rí wọn, a yóò sì tù ú nínú nítorí gbogbo ìjọ rẹ̀ tí a fi idà pa, ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
32 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti tan ẹ̀rù ká ilẹ̀ alààyè, Fáráò àti gbogbo ìjọ rẹ̀ ni a óò tẹ́ sí àárin aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”