15 Èmi kì yóò mú ki ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè mọ́, ìwọ kì yóò jìyà ọ̀rọ̀ ìfiṣẹ̀sín láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tàbí mú kí orílẹ̀ èdè rẹ ṣubú, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’ ”
16 Síwájú síi ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
17 “Ọmọ ènìyàn, nígbà tí àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì: ń gbé ní ilẹ̀ wọn, wọ́n bà á jẹ́ nípa ìwà àti ìṣe wọn. Ìwà wọn dàbí nǹkan àkókò àwọn obìnrin ni ojú mi.
18 Nítorí náà mo tú ìbínú mi jáde sórí wọn nítorí wọn ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ti fi ère wọn ba a jẹ́.
19 Mo tú wọn ká sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, a sì fọ́n wọn ká sí àwọn ìlú; mo ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti ìṣe wọn.
20 Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárin àwọn orílẹ̀ èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Olúwa, síbẹ̀ wọn ní láti fí ilẹ̀ náà sílẹ̀.’
21 Orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mi lógún, èyí tí ilé Ísírẹ́lì sọ di aláìmọ́ ni àárin àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti lọ.