Ísíkẹ́lì 36:30-36 BMY

30 Èmi yóò sọ èso àwọn igi yín àti ohun ọ̀gbìn oko yín di púpọ̀, nítorí kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jìyà ìdójútì mọ́ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè náà nítorí ìyàn.

31 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rántí àwọn ọ̀nà búburú àti àwọn ìwà ìkà yín, ẹ̀yin yóò sì korìíra ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ìwà tí kò bójúmu.

32 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì!

33 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ iwólulẹ̀

34 ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́.

35 Wọn yóò sọ wí pé, “Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ṣíṣòfo tẹ́lẹ̀ ti dà bí ọgbà Édẹ́nì; àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsìnyí.”

36 Nígbà náà àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà ní àyíká yín tí ó kù yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti tún àwọn ohun tí ó bàjẹ́ kọ́, mo sì ti tún ohun tí ó di ìṣòfò gbìn. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi yóò sì ṣe e?’