14 “ ‘Wọn yóò gbà àwọn ènìyàn ṣíṣẹ́ lóòrèkóórè láti ṣe àfọ̀mọ́ náà. Ọ̀pọ̀ yóò lọ káàkiri ilẹ̀ náà, ní àfikún pẹ̀lú wọn, àwọn tó kù yóò sìn àwọn tí ó kú lórí ilẹ̀: Ní ìparí oṣù kéje wọn yóò bẹ̀rẹ̀ wíwá kiri wọn.
15 Bí wọ́n n lọ káàkiri ilẹ̀ náà ọ̀kan nínú wọn rí egungun ènìyàn, oun yóò gbé àmì ńlá kalẹ̀ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ títí àwọn asìnkú yóò fi sìn ín ní àfonífojì Ámónì Gógì.
16 (Bákan náà ìlú kan tí a ń pè ni Ámónì yóò wà níbẹ̀). Nítorí náà wọn yóò wẹ ilẹ̀ náà:’
17 “Ọmọ ènìyàn èyí yìí ni ohun tí Olúwa Ọba wí pé: pe gbogbo oríṣìíríṣìí ẹyẹ àti gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́ jáde:” kí wọn pé jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè sí ìrúbọ tí mó ń múra rẹ̀ fún ọ, ìrúbọ ńlá náà ní orí òkè gíga tí Ísírẹ́lì. Níbẹ̀ ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀.
18 Ẹ̀yin yóò jẹ ẹran ara àwọn ènìyàn ńlá, ẹ o sì mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ aládé ayé bí ẹni pé wọn jẹ́ àgbò àti ọ̀dọ́ àgùntàn, ewúrẹ́ àti akọ màlúù gbogbo wọn jẹ́ ẹran Ọlọ́ràá láti Báṣánì
19 Níbi ìrúbọ tí mo ń múra kalẹ̀ fún yín, ẹ̀yin yóò jẹ ọ̀rá títí ẹ̀yin yóò fi jẹ àjẹkì, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ títí ẹ̀yin yóò fi yó.
20 Ní orí tábìlì mi ni àwa yóò ti fi ẹṣin àti ẹlẹ́sin bọ yín yó, pẹ̀lú àwọn alágbára ńlá àti oríṣìríṣìí jagunjagun ni Olúwa Ọba sọ.