19 Níbi ìrúbọ tí mo ń múra kalẹ̀ fún yín, ẹ̀yin yóò jẹ ọ̀rá títí ẹ̀yin yóò fi jẹ àjẹkì, ẹ̀yin yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ títí ẹ̀yin yóò fi yó.
20 Ní orí tábìlì mi ni àwa yóò ti fi ẹṣin àti ẹlẹ́sin bọ yín yó, pẹ̀lú àwọn alágbára ńlá àti oríṣìríṣìí jagunjagun ni Olúwa Ọba sọ.
21 “Èmi yóò ṣe àfihàn ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, gbogbo orílẹ̀ èdè yóò sì rí ìyà tí mo fi jẹ wọ́n.
22 Láti ọjọ́ náà lọ, ilé Ísírẹ́lì yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.
23 Àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí mi. Nítorí náà mo mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, mo sì fi wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, gbogbo wọn sì subú nípasẹ̀ idà.
24 Mo ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí àìmọ̀ àti àìṣedéédéé wọn, mo sì mú ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
25 “Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Ọba wí: Èmi yóò mú Jákọ́bù padà kúrò ní oko ẹrú, èmi yóò ní iyọ́nú si gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì, èmi yóò sì ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi.