26 Wọn yóò gbàgbé ìtìjú wọn àti gbogbo àìsòdodo tí wọ́n fihàn sí mi nígbà tí wọn ń gbé ni àìléwu ni ilẹ̀ wọn níbi tí kò ti sí ẹnìkẹ́ni láti dẹ́rù bà wọ́n.
27 Nígbà tí mo ti mú wọn padà kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè, tí mo sì kó wọn jọ pọ̀ kúrò ni ìlú àwọn ọ̀tá wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ wọn ní ojú àwọn orílẹ̀ èdè púpọ̀.
28 Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo rán wọn lọ sí ìgbèkùn láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, èmi yóò kó wọn jọ sí orí ilẹ̀ wọn, láì fi ìkankan sẹ́yìn.
29 Èmi kì yóò sì fi ojú mi pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn mọ nítorí èmi yóò tú èémí mi jáde sí ilé Ísírẹ́lì, ní Olúwa Ọba wí.”