3 Nígbà náà èmi yóò lu ọrùn awọ rẹ ní ọwọ́ òsì rẹ, èmi yóò sì mú kí àwọn ọfà rẹ jábọ́ ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
4 Ìwọ yóò sì subú ní orí àwọn òkè Ísírẹ́lì, ìwọ àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ àti gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn onírúurú ẹyẹ àti fún àwọn ẹranko igbó.
5 Iwọ yóò ṣubú ní gbangba pápá, nítorí tì mo ti sọ̀rọ̀, ni Olúwa Ọba wí.
6 Èmi yóò fi iná sí mágógì àti sí àwọn tí ń gbé ní agbègbè ilẹ̀ ibẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa.
7 “ ‘Èmi yóò sọ orúkọ mímọ́ mí di mí mọ̀ láàrin àwọn èniyàn mì Isìrẹli. Èmi ki yóò jẹ́ kí orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́ àwọn orílẹ èdè yóò mọ̀ pé èmi Olúwa, èmi ni ẹni mímọ́ ní Ísírẹ́lì.
8 Ó ń bọ̀! Ó dájú pé yóò ṣẹlẹ̀, ni Olúwa Ọba tẹnumọ́. Èyi yìí ni ọjọ́ tí mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
9 “ ‘Nígbà náà, àwọn ti ó ń gbé nì àárin àwọn ìlú tí ó wà ni Ísírẹ́lì yóò jáde, wọn yóò sì lo àwọn ohun ìjà bi epo ìdáná yóò sì jó wọ́n kanlẹ—àpáta kékèké àti àpáta ńlá, àwọn ọfà, àwọn kùmọ̀ ogun àti ọ̀kọ̀ fún ọdún méje wọn yóò lò wọ́n bi epo ìdáná.