6 “Tí o bá parí èyí, tún fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ kí o sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Júdà fún ogójì (40) ọjọ́, nítorí pé ọjọ́ kan ló dúró fún ọdún kan.
7 Dojú kọ ibùdó ogun Jérúsálẹ́mù, na ọwọ́ rẹ sí i, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú náà.
8 Èmi yóò dè ọ́ ní okùn débi pé ìwọ kò ní í le yírapadà láti ìhà ọ̀tún sí ìhà òsì títí tí ọjọ́ ìgbógun tì rẹ yóò fi pé.
9 “Mú ọkà bàbà àti àlìkámà, erèé àti lẹ́ńtìlì, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá.
10 Wọn òṣùnwọ̀n ogún (20) ṣékélì oúnjẹ tí ìwọ yóò máa jẹ-lójoojúmọ́ kí o sì máa jẹ ẹ́ ní àkókò tí a ti yà sọ́tọ̀.
11 Bákan náà, wọn ìdámẹ́fà hínì omi, kí ìwọ ó sì máa mú ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀.
12 Ìwọ yóò sì jẹ ẹ́ bí àkàrà báálì; dín in ní ojú àwọn ènìyàn, ìgbẹ́ ènìyàn ni kí o fi dáná rẹ.”