Ísíkẹ́lì 40:1-6 BMY

1 Ní ọdún kẹẹdọ́gbọ̀n tí a ti wà ni oko ẹrú wa, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún, ni oṣù kẹwàá ọdún kẹ́rinlá lẹ́yin ìsubú ìlú ńlá náà ní ọjọ́ náà gan an ọwọ́ Olúwa ń bẹ̀ lára mi, oùn sì mú mi lọ síbẹ̀.

2 Nínú ìran Ọlọ́run, ó mú mí lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ó sì gbé mi lọ sí orí òkè gíga fíofío. Ní ẹ̀gbẹ́ gúsù ọ̀pọ̀ ilé tó wà níbẹ̀ dàbí ìlú ńlá.

3 Ó mú mi lọ síbẹ̀, mo sì rí ọkùnrin kan tí ìrírí rẹ̀ dàbí ìrí bàba; ó dúró ni ẹnu ọ̀nà pẹ̀lú okùn aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun àti ọ̀pá ìwọnlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.

4 Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, wò pẹ̀lú ojú rẹ kí o sì gbọ́ pẹ̀lú etí rẹ, kí ó sì farabalẹ̀ sì gbogbo ohun tí mo máa fi hàn ọ, nítorí ìdí nìyí tí a fi mú ọ wá síhìn-ín. Sọ gbogbo ohun tí ó bá rí fún ilé Ísírẹ́lì.”

5 Mo rí ògiri tí ó yí agbègbè ibi mímọ̀ po. Gígùn ọ̀pá ìwọnlẹ̀ tí ó wà ní ọwọ́ ọkùnrin náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà, ọkọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ilásì mẹ́rin ẹsẹ̀ bàtà. Ó wọn ògiri náà; ó jẹ́ ìwọ̀nyí ọ̀pá náà ni níní ipọn, ó sì jẹ́ ọ̀pá kan ní gíga.

6 Lẹ́yìn náà ni ó wá lọ sí ẹnu ọ̀nà òde tí ó kọjú sí ìlà òòrùn. Ó gun àtẹ̀gùn rẹ̀, o sì wọn ìloro ẹnu ọ̀nà ilé; ó jẹ́ ọ̀pa kan ní jíjìn.