Ísíkẹ́lì 40:23-29 BMY

23 Ẹnu ọ̀nà kan sí àgbàlá ti inú ni àdojúkọ ẹnu ọ̀nà àríwá, gẹ́gẹ́ bí o ṣe wà ní ìlà òòrùn. Ó wọ̀n láti ẹnu ọ̀nà sí àdojúkọ ọ̀kan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

24 Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí ìhà gúsù, mo sì rí ẹnu ọ̀nà tí ó dojúkọ gúsù. Ó wọn àtẹ́rígbà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà, wọ́n jẹ́ bákan náà bí ti àwọn tí o kù.

25 Ẹnu ọ̀nà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ni ojú ihò tóóró yí po, gẹ́gẹ́ bí ojú ihò ti àwọn tókù. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ní fífẹ̀.

26 Àtẹ̀gùn méje ní ó dé ibẹ̀, pẹ̀lú àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ní òdì kejì wọn; Ó ní igi ọ̀pẹ tí a fi ṣe ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ni ojú ìgbéró ògiri ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan.

27 Àgbàlá ti inú náà ní ẹnu ọ̀nà yìí sí ẹnu ọ̀nà ìta ni ìhà gúsù; Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.

28 Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí àgbàlá ti inú láti ẹnu ọ̀nà gúsù, ó ní ìwọ̀n kan náà ẹnu ọ̀nà gúsù; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù.

29 Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà jẹ́ bákan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu ọ̀nà náà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ní ihò ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gbogbo