27 Àgbàlá ti inú náà ní ẹnu ọ̀nà yìí sí ẹnu ọ̀nà ìta ni ìhà gúsù; Ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́.
28 Lẹ́yìn náà, o mú mi lọ sí àgbàlá ti inú láti ẹnu ọ̀nà gúsù, ó ní ìwọ̀n kan náà ẹnu ọ̀nà gúsù; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù.
29 Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, àwọn ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà jẹ́ bákan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu ọ̀nà náà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ní ihò ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gbogbo
30 (Àwọn àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà tí ó yí àgbàlá po jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹẹdọ́gbọ̀n ni fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni jínjìn).
31 Àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ tí ó dojúkọ àgbàlá tí ìta, igi ọ̀pẹ ṣe ọ̀sọ́ sí àwọn àtẹ́rígbà rẹ̀, àtẹ̀gùn mẹ́jọ ní ó lọ sì òkè sí i.
32 Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí àgbàlá tí inú ni ìhà ilà òòrùn, ó sì wọn ẹnu ọ̀nà; ó ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù.
33 Àwọn yàrá kéékèèkéé rẹ̀, ìgbéró ògiri rẹ̀ àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ ní ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú àwọn tí ó kù. Ẹnu ọ̀nà náà àti àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà ni ihò yí po. Ó jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni fífẹ̀.