17 Ní ìta gbangba lókè ìta ẹnu ọ̀nà inú ibi mímọ́ àti lára ògiri pẹ̀lú àlàfo tí kò ju ara wọn lọ yípo inú ìta ibi mímọ́
18 ní wọn fín àwọn kérúbù àti àwọn igi ọ̀pẹ. Wọn fi àwọn igi ọ̀pẹ bo àárin àwọn kérúbù. Kérúbù kọ̀ọ̀kan ní ojú méjìméjì:
19 Ojú ènìyàn sí ìhà igi ọ̀pẹ ni ẹ̀gbẹ́ kan, ojú ọ̀dọ́ kìnnìún sí ìhà igi ọ̀pẹ ní ẹ̀gbẹ́ kejì. Wọn fín gbogbo rẹ̀ yípo gbogbo ilé Ọlọ́run.
20 Láti ilẹ̀ sí agbègbè òkè ẹnu ọ̀nà, àwọn Kérúbù àti àwọn igi ọ̀pẹ ni wọ́n fín si ara ògiri ìta ibi mímọ́.
21 Ìta ibi mímọ́ ni férémù onígun mẹ́rin pẹ̀lú ìkan tí ó wà ní ibi mímọ́ jùlọ rí bákan náà.
22 Pẹpẹ ìrúbọ kan tí a fi igi ṣe wà, gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, àwọn igun rẹ̀, ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti ògiri rẹ́ jẹ́ igi. Ọkùnrin náà sọ fún mi pé, “Èyí yìí ní tẹ́ḿpìlì tí ó wà ní iwájú Olúwa.”
23 Ìta ibi mímọ́ àti ibi mímọ́ jùlọ ni ilẹ̀kùn méjì papọ̀.