23 Ìta ibi mímọ́ àti ibi mímọ́ jùlọ ni ilẹ̀kùn méjì papọ̀.
24 Lẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan ní ewé méjìméjì, ewé méjì tí a gbe kọ́ fún ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan.
25 Ní ẹnu ilẹ̀kùn ní ìta ibi mímọ́ ni àwọn kérúbù àti igi ọ̀pẹ tí a fín bí ti àwọn tí a fín si àwọn ara ògiri, ìbòrí tí á fí igi ṣe wà ní iwájú ẹnu ọ̀nà ilé ní ìta.
26 Ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ògiri ẹnu ọ̀nà ní àwọn fèrèsé tóóró pẹ̀lú igi ọ̀pẹ tí a fín ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì wà. Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ilé Ọlọ́run náà ni ìbòrí tí a fi igi ṣe.