4 Ní iwájú àwọn ọ̀nà, yàrá wà nínú tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní fífẹ̀ tí ó sì jẹ́ ọgọ́ọrùn ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. Àwọn ilẹ̀kùn wọn wà ní apá ìhà àríwá.
5 Nísinsìn yìí àwọn yàrá òkè ṣe tóóró, nítorí ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè dàbí ẹni pé ó ní ààyè láti ara wọn ju láti ara àwọn yàrá ti ó wà ní ìsàlẹ̀ tàbí àárin ilé.
6 Àwọn yàrá tí ó wà ní àgbékà kẹta kò ni àwọn òpó gẹ́gẹ́ bí ilé ìdájọ́ ṣe ní; nítorí náà wọ́n kéré ni níní ààyè ju àwọn tí ó wà ní ìsàlẹ̀ àti àwọn àgbékà ti àárin.
7 Ògiri kan wà ní ìta tí ó ṣe déédé pẹ̀lú àwọn yàrá àti ìta ilé ìdájọ́; a fàá gùn ní iwájú àwọn yàrá ní àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́.
8 Nígbà tí ọ̀wọ́ yàrá ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kángun sí ìta ilé ìdájọ́ jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọ̀wọ́ ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ tí ó sún mọ́ ibi mímọ́ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn.
9 Yàrá ìsàlẹ̀ ni ẹnu ọ̀nà ní ìhà ìlà oòrùn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ṣe wọ inú rẹ̀ láti ìta ilé ìdájọ́.
10 Ní ìhà gúsù lọ sí ìbú ògiri ìta ilé ìdájọ́ tí o ṣe déédé pẹ̀lú àgbàlá ilé Ọlọ́run, ní òdìkejì ògiri ìta ni àwọn yàrá náà wà.