Ísíkẹ́lì 43:17-23 BMY

17 Igun ni apá òkè náà jẹ́ igun mẹ́rin lọ́gbọgba, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní gígùn, ó sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá ní fífẹ̀, pẹ̀lú etí tí ó jẹ́ ìdáji ìgbọ̀nwọ́, ìsàlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan yípo. Àtẹ̀gùn pẹpẹ ìrúbọ náà dojúkọ ìlà oòrùn.”

18 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, èyí yìí ni ohun tí Olúwa wí: Ìwọ̀nyí yóò jẹ́ òfin fún ìrúbọ ẹbọ sísun àti wíwọ́n ẹ̀jẹ̀ sórí pẹpẹ nígbà tí a bá mọ pẹpẹ tán:

19 Ẹ̀yin ní láti mú ọ̀dọ́ akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrékọjá fún àwọn àlùfáà, tí ó jẹ́ Léfì, tí ìdílé Sádókù tí ó wá sí agbègbè láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún mi ní Olúwa Ọba wí.

20 Ẹ ni láti mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí ẹ sì fi sórí ìwo mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà lórí pẹpẹ, àti lórí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ìjòkòó náà àti sí gbogbo etí rẹ̀ yípo, ìwọ yóò sì sọ pẹpẹ di mímọ́, ìwọ yóò sì ṣe ètùtù rẹ̀.

21 Ìwọ gbọdọ̀ mú akọ màlúù fún ìrékọjá, ìwọ yóò sì sun ún ní apá ibi tí a ṣàmì sí ní agbègbè ilé Ọlọ́run ní ìta ibi mímọ́.

22 “Ní ọjọ́ kejì ìwọ yóò fi ewúrẹ́, òbúkọ aláìlábàwọ́n fún ẹbọ ẹsẹ, a sì gbọdọ̀ sọ pẹpẹ di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ́ di mímọ́ pẹ̀lú akọ màlúù.

23 Nígbà tí ìwọ bá parí ìsọdimímọ́, ìwọ yóò fi ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ọ̀dọ́ àgbò aláìlábàwọ́n láti inú agbo fún ìrúbọ.