27 Ní ọjọ́ ti yóò wọ àgbàlá ti inú ni ibi mímọ́ láti se ìránṣẹ́ ibi mímọ́, ni kí òun kí o rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni Olúwa Ọba wí.
28 “ ‘Èmi ni kì ó jẹ́ ogún tí àwọn Àlùfáà yóò ní. Ẹ kò gbọdọ̀ fún wọn ni ìpín kankan ní Ísírẹ́lì; Èmi ni yóò jẹ́ ìpín wọn.
29 Wọn yóò jẹ ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; gbogbo ohun tí a bá yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ni Ísírẹ́lì ni yóò jẹ́ ti wọn.
30 Èyí tí ó dára jùlọ nínú gbogbo àkọ́so èso àti ti ẹ̀bùn pàtàkì yóò jẹ́ ti àwọn àlùfáà. Ẹ ní láti fún wọn ní ìpín àkọ́kọ́ nínú èso ilẹ̀ yìí kí ìbùkún lè wà lórí gbogbo ilé yìí.
31 Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ jẹ́ ohunkóhun bí i ẹyẹ tàbí ẹrankọ, tí ó ti kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí ti ẹranko ńlá fà ya.