Ísíkẹ́lì 46:3-9 BMY

3 Ní àwọn ọjọ́ ìsinmi àti àwọn oṣù tuntun ni kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ́sìn ní iwájú Olúwa ní àbáwọlé ẹnu ọ̀nà.

4 Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmí ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù.

5 Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ éfà kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú éfà kọ̀ọ̀kan.

6 Àti ni ọjọ́ oṣù tuntun, ẹgbọrọ màlúù kan àìlábàwọ́n, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́fà, àti àgbò kan: wọn o wà láìlábàwọ́n.

7 Yóò si pèsè ọrẹ-ẹbọ jíjẹ éfà fun ẹgbọrọ akọ màlúù, àti éfà kan fun àgbò kan, àti fun àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bi èyí ti ipá rẹ̀ ká, àti hínì òróró kan fún éfà kan.

8 Nígbà tí ọmọ aládé bá wọlé, ó gbọdọ̀ gbá àtẹ̀wọ̀ ẹnu ọ̀nà wọ inú, kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.

9 “ ‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá ṣíwájú Olúwa ni àwọn àjọ tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu ọ̀nà ìhà gúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gba tí ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé padà, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde.