12 Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò dàgbà ní bèbè odò méjèèjì. Ewé wọn kì yóò sì gbẹ, tàbí ní èso nítorí pé odò láti ibi mímọ́ ń ṣàn sí wọn. Èso wọn yóò dàbí oúnjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.”
13 Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Ọba wí: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárin àwọn ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì, pẹ̀lú ìpín méjì fún Jóṣéfù.
14 Ìwọ yóò pín ilẹ̀ náà déédéé ní àárin wọn. Nítorí pé mo búra nípa nína ọwọ́ sókè láti fi fún àwọn baba ńlá yin, ilẹ̀ yìí yóò di ogún ìní yín.
15 “Èyí yìí ni yóò jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà:“Ní ìhà àríwá yóò lọ láti omi òkun ńlá ní ibi ọ̀nà Hétílónì gbà tí Hámátì sí Sídádì,
16 Bérótalì àti Síbíráímù (èyí tí ó wà ní ààlà láàárin Dámáskù àti Hámátì) títí dé Hásà Hátíkọ, èyí tí ó wà ní ààlà Háúránù.
17 Ààlà yóò fẹ̀ láti òkun lọ sí Hásà Énánù, ní apá ààlà ti Dámáskù, pẹ̀lú ààlà tí Hámátì lọ sí apá àríwá. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà ní apá ìhà àríwá.
18 “Ní ìhà ìlà oòrùn ààlà yóò wá sí àárin Háúránù àti Dámásíkù, lọ sí apá Jọ́dánì láàárin Gílíádì àti ilẹ̀ oòrùn àti títí dé Támárì. Èyí ní yóò jẹ́ ààlà ìlà oòrùn.