2 Ó wá mú mi gba ojú ọ̀nà àríwá jáde, ó sì mú mi yí ìta ojú ọ̀nà ìta tí ó dojúkọ ìhà ìlà oòrùn, omi náà sì ń ṣàn láti ìhà gúsù wá.
3 Bí ọkùnrin náà ti lọ sí apá ìhà ìlà oòrùn pẹ̀lú okùn wíwọ̀n nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, o wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi gba ibi odò kan tí kòì jìnjù kókósẹ̀ lọ.
4 Ó sì wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba ibi odò tí o jìn ní ìwọ̀n orúnkún. Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba odò tí ó dé ìbàdí.
5 Ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ṣùgbọ́n nísinsìnyí odò tí ń kò lè kọjá rẹ̀ ni, Nítorí pé odò tí ó kún, ó sì jìn tó èyí tí wọ́n le lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ odò tí ẹnikẹ́ni kò le dá kọjá ni.
6 Ó bi mí léèrè, pé: “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ o rí èyí?”Lẹ́yìn náà ó mú mi padà sí etí odò.
7 Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì odò.
8 Ó sọ fún mi pé, “Odò yìí ń ṣàn sí ìhà ìlà oòrùn, ó sì lọ sí ìsàlẹ̀ títí dé Árábù, níbi tí ó ti wọ inú òkun, omi tí o wà níbẹ̀ jẹ́ èyí tí ó tutù.