6 Ó bi mí léèrè, pé: “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ o rí èyí?”Lẹ́yìn náà ó mú mi padà sí etí odò.
7 Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì odò.
8 Ó sọ fún mi pé, “Odò yìí ń ṣàn sí ìhà ìlà oòrùn, ó sì lọ sí ìsàlẹ̀ títí dé Árábù, níbi tí ó ti wọ inú òkun, omi tí o wà níbẹ̀ jẹ́ èyí tí ó tutù.
9 Àwọn ohun alààyè tí o ń rákò yóò máa gbé ní íbikíbi tí odò ti ń ṣàn. Ẹja yóò pọ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀, nítorí pé odò ń ṣàn síbẹ̀ ó sì mú kí omi iyọ̀ tutù nini; nítorí náà níbi tí omi ti ń ṣàn gbogbo nǹkan ni yóò wà ni ààyè.
10 Àwọn apẹja yóò dúró ní etí bèbè odò; láti Éńgédì títí dé Énégíláémù àyè yóò wa láti tẹ́ àwọ̀n wọn sílẹ̀. Orísìírísìí ẹja ni yóò wà gẹ́gẹ́ bí ẹja omi òkun ńlá.
11 Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò; àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀.
12 Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò dàgbà ní bèbè odò méjèèjì. Ewé wọn kì yóò sì gbẹ, tàbí ní èso nítorí pé odò láti ibi mímọ́ ń ṣàn sí wọn. Èso wọn yóò dàbí oúnjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.”