Ísíkẹ́lì 48:20-26 BMY

20 Gbogbo ìpín náà yóò rí bákan náà ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, èyí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ẹgbẹ kọ̀ọ̀kan. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì ìwọ yóò fi ìpín ibi mímọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kan, papọ̀ mọ́ ohun ìní ìlú ńlá náà.

21 “Èyí tí ó sẹ́kù ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì agbégbé tí ó jẹ́ ìpín ibi mímọ́ àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ aládé. Yóò lọ títí dé ìhà ìlà oòrùn láti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ti ìpín ibi mímọ́ títí dé ààlà ìlà oòrùn. Agbégbé méjèèjì wọ̀nyí ni gígùn àwọn ìpín ẹlẹ́yàmẹ́yà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ aládé, àti ìpín ibi mímọ́ pẹ̀lú tẹ́ḿpìlì yóò wa ní àárin wọn.

22 Ilẹ̀ ìní àwọn Léfì àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò wà ni àárin agbégbé tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ aládé. Agbégbé tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ aládé yóò wà ní àárin ààlà tí Júdà àti ààlà tí Bénjámínì.

23 “Níti àwọn ẹ̀yà tí ó kù: Bẹ́ńjámínì yóò ní ìpín kan; Yóò wà láti ìhà ìlà oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀ oòrùn.

24 “Símónì yóò ní ìpín kan: Yóò jẹ́ ààlà agbégbé Bẹ́ńjámínì láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn.

25 “Ísàkárì yóò ní ìpín kan: yóò jẹ́ ààlà agbégbé Símónì láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn.

26 “Sébúlónì yóò ní ìpín kan; yóò jẹ́ ààlà agbégbé Isàkárì láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn.