22 Ilẹ̀ ìní àwọn Léfì àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò wà ni àárin agbégbé tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ aládé. Agbégbé tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ aládé yóò wà ní àárin ààlà tí Júdà àti ààlà tí Bénjámínì.
23 “Níti àwọn ẹ̀yà tí ó kù: Bẹ́ńjámínì yóò ní ìpín kan; Yóò wà láti ìhà ìlà oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀ oòrùn.
24 “Símónì yóò ní ìpín kan: Yóò jẹ́ ààlà agbégbé Bẹ́ńjámínì láti ìlà oòrùn lọ sí ìwọ̀ oòrùn.
25 “Ísàkárì yóò ní ìpín kan: yóò jẹ́ ààlà agbégbé Símónì láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn.
26 “Sébúlónì yóò ní ìpín kan; yóò jẹ́ ààlà agbégbé Isàkárì láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn.
27 “Gádì yóò ní ìpín; yóò jẹ́ ààlà agbégbé Sébúlónì láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn.
28 “Ààlà tí gúsù Gádì yóò dé gúsù láti Támárì lọ sí odò Méríbà Kádésì lẹ́yìn náà títí dé Wádì ti Éjíbítì lọ sí òkun ńlá fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ìwọ̀nyí ní yóò sì jẹ́ ìpín wọn” ní Olúwa Ọba wí.