6 Òpin ti dé! Òpin ti dé, ó ti dìde lòdì sí ọ. Ó ti dé!
7 Ìparun ti dé sórí yín gbogbo, ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ náà. Àsìkò ti tó, ọjọ́ wàhálà ti súnmọ́ etílé; kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí òkè.
8 Mo ṣetán láti tú ìbìnú gbígbóná mi lé ọ lórí àti láti lo ìbínú mi lórí rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ, n ó sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bi gbogbo ìwà ìríra rẹ.
9 Ojú mi kò ní i dá ọ sí, ń kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú; ń o san-an fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà ìwà àti gbogbo ìwà ìríra tí wà láàrin rẹ. Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé èmi Olúwa lo kọlù yín.
10 “Ọjọ́ náà ti dé! O ti dé: Ìparun ti bú jáde, ọ̀pá ti tan ná, ìgbéraga ti sọ jáde!
11 Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú; kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kú, tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, kò sí ọrọ̀ ko si ohun ti o niye.
12 Àsìkò náà ti tó; ọjọ́ náà tidé, kí ẹni tó n rajà má se yọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ki ontàjà má ṣe ṣọ̀fọ̀; torí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn.