1 Ní ọjọ́ karùn-ún (5), oṣù kẹfà (6) ọdún kẹfà (6) bí mo ṣe jókòó nílé mi pẹ̀lú àwọn àgbààgbà Júdà níwájú mi, ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run bà lé mi níbẹ̀.
2 Nígbà tí mo wò, mo rí ohun kan tí o jọ ènìyàn. Láti ibi ìbàdí rẹ lọ sísàlẹ̀ dàbí iná, láti ibi ìbàdí yìí sókè sì mọ́lẹ̀ bí idẹ tó ń kọ mọ̀nà.
3 Ó na ohun tó dàbí ọwọ́ jáde, ó fi gba mi nírun orí mú, Ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede-méjì ayé àti ọ̀run, ó sì mú mi lọ rí ìran Ọlọ́run, mo sì lọ sí Jérúsálẹ́mù, sí ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà òde àríwá níbi tí ère tí ó ń mú ni bínú wá níwájú mi,
4 Sì kíyèsíi, ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìran ti mo rí ni pẹ̀tẹ́lẹ̀
5 Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbójú sókè sí ìhà àríwá.” Èmi náà sì gbójú sókè sí ìhà àríwá mo sì rí ère tí ó ń mú ni jowú ní ẹnu ọ̀nà ibi pẹpẹ.