10 Mo wọlé, mo sì rí àwòrán oríṣìíríṣìí ẹranko tí ń fà nílẹ̀ àti àwọn ẹranko ìríra àti gbogbo òrìṣà ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí wọ́n yà sára ògiri.
11 Níwájú wọn ni àádọ́rin (70) ọkùnrin tó jẹ́ àgbà ilé Ísírẹ́lì dúró sí, Jáásáníà ọmọ Sáfánì sì dúró sáàrin wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde.
12 Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì ń ṣe nínú òkùnkùn, olúkúlùkù ní yàrá òrìṣà rẹ̀? Wọ́n ní, ‘Olúwa kò rí wa; Olúwa ti kọ̀ ilé náà sílẹ̀.’ ”
13 Ó tún sọ fún mi pé, “Ìwọ yóò rí wọn tí wọ́n ń ṣe àwọn ohun mìíràn tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
14 Ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sí ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ fún Támúrì.
15 Ó sọ fún mi pé, “Ṣé o rí báyìí, ọmọ ènìyàn? Ìwọ yóò tún rí ìríra tó ga jù èyí lọ.”
16 Ó mú mi wá sí ibi àgbàlá ilé Olúwa, lẹ́nu ọ̀nà tẹ́ḿpìlì Olúwa, wọn kọjú sí ìlà òòrùn, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún òòrùn ní apá ìlà òòrùn.