7 Ó mú mi wá sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá. Mo wò ó, mo sì rí ihò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri.
8 Nígbà náà ló sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbẹ́ inú ògiri náà,” nígbà tí mo sì gbẹ́ inú ògiri, mo rí ìlẹ̀kùn kan.
9 Ó sì wí fún mi pé, “Wọlé kí o rí ohun ìríra búburú tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀.”
10 Mo wọlé, mo sì rí àwòrán oríṣìíríṣìí ẹranko tí ń fà nílẹ̀ àti àwọn ẹranko ìríra àti gbogbo òrìṣà ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí wọ́n yà sára ògiri.
11 Níwájú wọn ni àádọ́rin (70) ọkùnrin tó jẹ́ àgbà ilé Ísírẹ́lì dúró sí, Jáásáníà ọmọ Sáfánì sì dúró sáàrin wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde.
12 Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Ísírẹ́lì ń ṣe nínú òkùnkùn, olúkúlùkù ní yàrá òrìṣà rẹ̀? Wọ́n ní, ‘Olúwa kò rí wa; Olúwa ti kọ̀ ilé náà sílẹ̀.’ ”
13 Ó tún sọ fún mi pé, “Ìwọ yóò rí wọn tí wọ́n ń ṣe àwọn ohun mìíràn tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ.”