Nọ́ḿbà 11:13-19 BMY

13 Níbo ni n ó ti rí ẹran fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Nítorí wọ́n ń sunkún sí mi pé, ‘Fún wa lẹ́ran jẹ́!’

14 Èmi nìkan kò lè dá gbé wàhálà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹrù wọn ti wúwo jù fún mi.

15 Bí ó bá sì ṣe pé báyìí ni ìwọ ó ṣe máa ṣe fún mi, kúkú pa mí báyìí, tí mo bá ti bá ojú rere rẹ pàdé—kí ojú mi má ba à rí ìparun mi.”

16 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé: “Mú àádọ́rin (70) ọkùnrin nínú àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn tí o mọ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí àti olóyè láàrin àwọn ènìyàn wá sínú Àgọ́ Ìpàdé, kí wọ́n lé dúró níwájú mi.

17 Èmi ó sì sọ̀kalẹ̀ wá bá yín sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Èmi ó sì mú nínú Ẹ̀mi tí ń bẹ lára rẹ láti fi sí orí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru àjàgà àwọn ènìyàn kí ó má ṣe pé ìwọ nìkan ni ó o máa ru àjàgà náà.

18 “Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé: ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún ọ̀la, ẹ ó sì jẹ ẹran. Nítorí pé Olúwa ti gbọ́ igbe ẹkún yín, èyí tí ẹ sun pé, “Ìbá ṣe pé a lè rí ẹran jẹ ni! Ó sàn fún wa ní Éjíbítì jù báyìí lọ!” Nítorí náà ni Olúwa yóò fi fún yín ní ẹran, ẹ ó sì jẹ ẹ́.

19 Ẹ kò ní i jẹ ẹ́ fún ọjọ́ kan, ọjọ́ méjì, ọjọ́ márùn-ún, ọjọ́ mẹ́wàá tàbí ogúnjọ́ lásán,