1 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti àwọn ọmọ Gádì, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn àti ohun ọ̀sìn rí wí pé ilé Jásérì àti Gádì dára fún ohun ọ̀sìn.
2 Nígbà náà wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Mósè àti Élíásárì àlùfáà àti sí olórí gbogbo ìlú, wọ́n sì wí pé,
3 “Átarótì, Díbónì, Jásérì, Nímírà, Hésíbónì, Élíálì, Sébámù, Nébò, àti Béónì.
4 Ni ilẹ̀ tí Olúwa ti ṣẹ́gun níwájú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì tí ó sì dára fún ohun ọ̀sìn, ṣáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ohun ọ̀sìn.
5 Tí a bá rí ojú rere rẹ,” wọ́n wí, “jẹ́ kí a fi ilẹ̀ yìí fún ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní. Má se jẹ́kí a rékọjá odò Jọ́dánì.”
6 Mósè sọ fún àwọn ọmọ Gádì àti fún ọmọ Rúbẹ́nì pé, “Ṣé kí àwọn arákùnrin yín lọ sí ogun, kí ẹ̀yin kí ó sì jókó sí bí?
7 Kí ni ó dé tí o fi mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti lọ sí ibi ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn?
8 Èyí ni nǹkan tí baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadesi-Báníyà láti lọ wo ilẹ̀ náà.
9 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ sí Àfonífojì Ésíkólù tí wọ́n rí ilẹ̀ náà, wọ́n mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn.
10 Ìbínú Olúwa sì dìde sí wọn ní ọjọ́ náà, ó sì búra, wí pé:
11 ‘Nítorí wọn kò tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó gòkè láti Éjíbítì ni yóò rí ilẹ̀ tí mo pinnu gẹ́gẹ́ bí ìbúra fún Ábúráhámù, fún Ísáákì àti fún Jákọ́bù:
12 kò sí ẹnìkankan àyàfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ti Kénísì àti Jóṣúà ọmọ Núnì, nítorí wọ́n tẹ̀lé Olúwa tọkàntọkàn.’
13 Ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì mú wọn rìn ní ihà fún ogójì (40) ọdún, títí tí àwọn ìran tí wọ́n ṣe búburú ní ojú rẹ̀ fi lọ.
14 “Níbí ni ẹ̀yin wà, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ̀yin dìde ní ipò bàbá yín, ẹ sì jẹ́ kí ìbínú gbígbóná Olúwa ru sí Ísírẹ́lì.
15 Tí ẹ̀yin bá yípadà ní ẹ̀yìn rẹ̀ yóò sì fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí sílẹ̀ ní ihà, ìwọ yóò sì mú-un ṣe ìparun.”
16 Nígbà náà wọ́n wá sí òkè ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, “Àwa yóò fẹ́ láti kọ́ ilé ẹran níhínyìí fún ohun ọ̀sìn wa, àti ìlú fún àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa.
17 Ṣùgbọ́n àwa ṣetán láti dira ogun ṣááju àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí tí a yóò fi mú wọn dé ọ̀dọ̀ wọn lákokò yìí, àwọn obìnrin àti ọmọ wẹ́wẹ́ wa yóò gbé inú ìlú tí a mọ odi sí fún ìdábòbò wọn lọ́wọ́ olùgbé ilẹ̀ náà.
18 A kì yóò padà sí ilẹ̀ wa láì ṣe pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti gba ogún wọn.
19 A kì yóò gba ogún kankan pẹ̀lú wọn ní òdìkejì Jọ́dánì, nítorí ogún ti wa, ti wá sí ọ̀dọ̀ wa ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì.”
20 Nígbà náà ni Mósè sọ fún wọn pé, “Tí ẹ̀yin yóò bá pa ara yín lára, níwájú Olúwa fún ogún.
21 Bí gbogbo yín yóò bá lọ sí Jọ́dánì ní ìhámọ́ra níwájú Olúwa, títí yóò fi lé àwọn ọ̀ta rẹ̀ kúrò níwájú rẹ̀.
22 Tí a ó sì fi ṣe ilẹ̀ náà níwájú Olúwa; ẹ̀yin lè padà tí yóò sì di òmìnira lọ́wọ́ ìdè níwájú Olúwa àti Ísírẹ́lì. Ilẹ̀ yìí yóò sì jẹ́ ti yín níwájú Olúwa.
23 “Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kọ̀ láti ṣe èyí, ẹ̀yin yóò máa dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa; kí ẹ̀yin kí ó sì mọ̀ dájú pé ẹ̀ṣẹ̀ yín yóò fi yín hàn.
24 Ẹ kọ́ ilé fún àwọn obìnrin yín àti ọmọ wẹ́wẹ́ yín, àti ilé fún agbo ẹran yín, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó ṣe ohun tí ẹ ti pinnu.”
25 Àwọn ọmọ Gádì àti ọmọ Rúbẹ́nì sọ fún Mósè pé, “Àwa ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa wa ti paláṣẹ.
26 Àwọn ọmọ wa àti ìyàwó wa, àwọn agbo ẹran àti ohun ọ̀sìn wa yóò dúró ní ìlú Gílíádì.
27 Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gbogbo ọkùnrin tí ó wọ ìhámọ́ra ogun, yóò ré kọjá lọ láti jà níwájú Olúwa; gẹ́gẹ́ bí olúwa wa ti sọ.”
28 Nígbà náà ni Mósè pàṣẹ nípa wọn fún Élíásárì àlùfáà àti Jóṣúà ọmọ Núnì àti sí gbogbo olórí ìdílé ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
29 Ó wí fún wọn pé, “Tí àwọn ọmọ Gádì àti ọmọ Rúbẹ́nì, gbogbo ọkùnrin tí ó wọ ìhámọ́ra fún ogun rékọjá odò Jọ́dánì pẹ̀lú níwájú Olúwa, nígbà tí ẹ ṣegun ilẹ̀ náà níwájú yín, Fún wọn ní ilẹ̀ Gílíádì gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.
30 Ṣùgbọ́n tí wọn kò bá fẹ́ bá yín rékọjá pẹ̀lú ìhámọ́ra, wọn gbọdọ̀ gba ìní wọn pẹ̀lú yín ní Kénánì.”
31 Àwọn ọmọ Gádì àti ọmọ Rúbẹ́nì dáhùn pé, “Iránṣẹ́ rẹ yóò ṣe ohun tí Olúwa ti sọ.
32 A máa rékọjá níwájú Olúwa lọ sí Kénánì pẹ̀lú ìhámọ́ra, ṣùgbọ́n ẹrù tí a jogún yóò wà ní ẹ̀bá Jọ́dánì.”
33 Nígbà náà Mósè fún àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ọmọ Jóṣẹ́fù ìjọba Ṣíhónì ọba àwọn ọmọ Ámórì àti ìjọba Ógù ọba Básánì ní gbogbo ilẹ̀ náà pẹ̀lú ìlú rẹ̀ àti agbégbé tí ó yí i ka.
34 Àwọn ará Gádì wọ́n kọ́ Dídónì, Átarótù, Áróérì;
35 Pẹ̀lú Átírótù Ṣófánì, Jásérì, àti Jógbénà:
36 Pẹ̀lú Bétínímírà, àti Bétí-Áránì ìlú olódi, àti agbo fún àgùntàn.
37 Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì sì kọ́ Hésíbónì, Élíálì, Kíríátaímù,
38 pẹ̀lú Nébò pẹ̀lú Báálì-Méónì, (“Wọ́n pàrọ̀ orúkọ wọn”) àti Síbímà. Wọ́n sì sọ ìlú tí wọ́n tún kọ́ ní orúkọ mìíràn.
39 Àwọn ọmọ Mákírì ọmọ Mánásè lọ sí Gílíádì, wọ́n sì lé àwọn ọmọ Ámórì tí ó wà níbẹ̀.
40 Mósè sì fi àwọn ọmọ Gílíádì fún àwọn ọmọ Mákírì àwọn ìrán Mánásè, wọ́n sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀.
41 Jáírì, ọmọ Mánásè gba ibùjókòó wọn, ó sì pè wọ́n ní Háfótù Jáírì.
42 Nébà gbà Kénátì àti àwọn ìtẹ̀dó rẹ̀, ó sì pè é ní Nóbà lẹ́yìn orúkọ ara rẹ̀.