Nọ́ḿbà 31 BMY

Gbígbẹ̀san Lára Àwọn Ọmọ Mídíánì.

1 Olúwa sọ fún Mósè pé,

2 “Gbẹ̀san lára àwọn Mídíánì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn ìgbà náà a ó kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ.”

3 Mósè sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wọ ìhámọ́ra ogun fún àwọn kan nínú yín láti lọ da ojú ìjà kọ àwọn ọmọ Mídíánì láti gba ẹ̀san Olúwa lára wọn.

4 Rán ẹgberún (1000) ọmọ ogun láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní Ísírẹ́lì.”

5 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yan nínú àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún (1000) ènìyan láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ènìyàn tí ó wọ ìhámọ́ra ogun.

6 Mósè rán wọn lọ sí ogun, ẹgbẹ̀rún (1000) láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú Fínéhásì ọmọ Élíásárì, ti ó jẹ́ àlùfáà, ti òun ti ohun èlò ibi mímọ́ àti ìpè wọ̀n-ọn-nì ní ọwọ́ rẹ̀.

7 Wọ́n dojú ìjà kọ Mídíánì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti láṣẹ fún Mósè, kí wọn sì pa gbogbo wọn.

8 Wọ́n sì pa àwọn ọba Mídíánì pẹ̀lú: àwọn ìyókù tí wọ́n pa lára wọn ni Éfì, Rékémù, Ṣúrù àti Húrì, àti Rébà: ọba Mídíánì márùn ún, wọ́n sì fi idà pa Bálámù ọmọ Béórì.

9 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì mú gbogbo obìnrin Mídíánì ní ìgbékùn àti àwọn ọmọ kékeré wọn, wọ́n sì kó gbogbo ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo agbo ẹran wọn àti gbogbo ẹrù wọn.

10 Wọ́n finá jó gbogbo ìlú wọn àti ibùdó wọn.

11 Wọ́n sì kó gbogbo ìní wọn, àti ènìyàn àti ẹran.

12 Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí wọ́n bàjẹ́ àti ènìyàn àti ẹran wá sọ́dọ̀ Mósè àti Élíásárì àlùfáà, àti sọ́dọ̀ ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ibùdó àgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò.

13 Mósè, Élíásárì àlùfáà àti gbogbo olórí ìgbéríko lọ láti lọ bá wọn ní ìta ibùdó.

14 Inú bí Mósè sí àwọn olórí ọmọ ogun, pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹ̀rún (1000) àti olórí ọrọrún (1000) tí wọ́n ti ogun dé.

15 Mósè sì bèèrè wí pé, “Ẹ̀yin ha dá gbogbo àwọn obìnrin sí bí?

16 Àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Bálámù, àwọn ní ó ṣe okùnfà yíyí àwọn ọ̀mọ̀ Ísírẹ́lì padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa nínú èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Péórì, nibi tí àjàkálẹ̀-àrùn ti kọlu àwọn ènìyàn Olúwa.

17 Nísinsìnyìí, pa gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó ti súnmọ́ ọkùnrin,

18 Ṣùgbọ́n kí o dá obìnrin tí kò bá tí ì sún mọ́ ọkùnrin sí fún ara yín.

19 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti pa ènìyàn tàbí fọwọ́ kan ẹni tí a pa gbọdọ̀ dúró ní ìta ibùdó àgọ́ fún ọjọ́ méje, Ní ọjọ́ kẹ́ta àti ọjọ́ kéje ẹ gbọdọ̀ ya ara yín àti ẹni tí ẹ kó lẹ́rú sí mímọ́.

20 Kí ẹ̀yin kí ó ya aṣọ yín sí mímọ́ àti gbogbo ohun tí a fi awọ ṣe àti gbogbo iṣẹ́ irun ewúrẹ́ àti ohun tí a fi igi ṣe.”

21 Élíásárì àlùfáà sì wí fún àwọn olórí ogun náà pé, “Èyí ní ìlànà òfin tí Olúwa fi lélẹ̀ ní àṣẹ fún Mósè.

22 Kìkì i wúrà, fàdákà, idẹ, irin, tanńganran àti òjé.

23 Ohunkóhun tí ó lè la iná ni kí ẹ̀yin ó mú la iná, nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n ẹ ó ò fi omi ìyàsímímọ́ sọ ọ́ di mímọ́. Àti gbogbo ohun tí kò lè la iná kọjá ni kí a mú la inú omi.

24 Ní ọjọ́ kéje, ẹ fọ aṣọ yín, ẹ̀yin yóò sì mọ́, nígbà náà ní ẹ̀yin yóò lè wọ inú ibùdó àjọ.”

Pínpín ogún.

25 Olúwa sọ fún Mósè pé,

26 “Ìwọ àti Élíásárì àlùfáà àti àwọn olórí ilé baba ìjọ ni kí o ka iye àwọn ènìyàn àti ẹranko tí a kó ní ìgbékùn.

27 Pín ohun ìní àti ìkógún náà láàrin àwọn ọmọ ogun náà tí ó kópa nínú ogun náà àti láàrin gbogbo ìjọ.

28 Kí o sì gba ìdá ti Olúwa lọ́wọ́ àwọn ológun tí wọn jáde lọ sí ogun náà: ọ̀kan nínú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nínú àwọn ènìnyàn àti nínú màlúù àti nínú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti nínú agbo ẹran.

29 Gbà ìdá yìí lára ààbọ̀ ìpín ti wọn, kí o sì fún Élíásárì àlùfáà, fún ẹbọ ìgbésókè Olúwa.

30 Lára ààbọ̀ ti Ísírẹ́lì, yan ọ̀kan kúrò nínú àádọ́ta, (50) yálà ènìyàn, ẹran ọ̀sìn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹ̀yà ẹranko mìíràn. Kó wọn fún àwọn Léfì, tí ó dúró fún olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.”

31 Nígbà náà Mósè àti Élíásárì àlùfáà ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mósè.

32 Èrè tí ó kù lára ìkógun tí àwọn ọmọ ogun kó jẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (675,000) ó dín ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àgùntàn.

33 Ẹgbàá mẹ́rìndínlógójì (72,000) màlúù

34 ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rin (61,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,

35 Pẹ̀lú obìnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógún, (32,000) ni kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí.

36 Ìpín ààbọ̀ àwọn tí ó jáde lọ sí ogun sì jẹ́:ẹgbàá méjìdínláàdọ́san (337,500) ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ àgùntàn.

37 Tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (675) àgùntàn;

38 ẹgbọ̀rọ̀ màlúù jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógún, (36,000) tí ìdá Olúwa sì jẹ́ méjìléláàdọ́rin (72);

39 kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún, ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta, (30,500) tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ mọ́kànlélọ́gọ́ta; (61).

40 Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ (16,000) ìdá ti Olúwa sì jẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n. (32)

41 Mósè fi ìdá náà fún Élíásárì, àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìdá ti Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.

42 Ààbọ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí Mósè yà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọkùnrin tí ó ja ogun.

43 (Ààbọ̀ tí àwọn ará ìlú sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínláàdọ́sàn-án ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn,

44 pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000) màlúù

45 tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (30,500)

46 Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ;) (16,000).

47 Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Mósè yan ọ̀kan lára àádọ́ta (50) ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.

48 Pẹ̀lú àwọn olórí tí ó wà lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rin ogun náà, àti àwọn balógun ọrọọrún wá sọ́dọ̀ Mósè.

49 Wọ́n sì sọ fún un pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti ka àwọn ọmọ ogun náà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú wa, kò sì sí ìkọkan tó dín.

50 Nítorí náà làwa ṣe mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, gbogbo ọrẹ wíwà tí a ní, wúrà, ẹ̀wọ̀n, àti júfù, àti òrùka: àmi, àti òrùka etí, àti ìlẹ̀kẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ọkàn an wa níwájú Olúwa.”

51 Mósè àti Élíásárì àlùfáà, gba wúrà náà lọ́wọ́ ọ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun iṣẹ́ ọ̀ṣọ́.

52 Gbogbo wúrà tí àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún mú wá fún Mósè àti Élíásárì, èyí tí ó jẹ́ ẹbọ ìgbésókè fún Olúwa jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé àádọ́ta (16,750) ṣékélì.

53 Nítorí ológun kọ̀ọ̀kan ti kó ẹrù fún ara rẹ̀.

54 Mósè àti Élíásárì àlùfáà gba wúrà náà lọ́wọ́ àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti lọ́wọ́ balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wọ́n sì ko wá sínú Àgọ́ Ìpàdé fún ìrántí àwọn Ísírẹ́lì níwájú Olúwa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36